Showing posts with label OSELU. Show all posts
Showing posts with label OSELU. Show all posts

07/12/2015

Egbe APC Kaduna pin si meji.


Egbe All Progressive government(APC) ipinle Kaduna ni o ti pin si meji lehin nnkan bi osu mefa ti egba naa gbajoba ipinle ohun. Gege bi iroyin se so, egbe titun naa ni o ni awon eniyan jànkan bii akowe ijoba tele, Dr Hakeem Baba-Ahmed, Alaga ANPP tele, Alhaji Kabir Umar, koomisoanna tele eto eko,  ogbeni Tom mataimaki Maiyashi, Alhaji Lawal     Maiturare, Nasiru Ahmed ati Murtala Abubakar.
Egbe titun naa ni na ni won pe oruko re ni ‘True APC’ ti awon omo egbe naa si fesun kan ijoba Gomina Nasir El-Rufai, pe ijoba okunrin naa ni on se ohun ti o yato si ohun ti egbe awon duro fun. Gege bi egbe titun naa ti so, iyato(Change) ni egbe naa duro fun, ti awon ara ilu si ye ko ri iyato naa ninu ijoba egbe awon, sugbon ti ijoba Nasir El-Rufai  ko tele ilana egbe naa.
Sa, awon olori egbe APC ni o ti fowosi awon ilana  ti Gomina Nasir El-Rufai n tele pe o ba ilana egbe awon mu.

20/11/2015

Egbe Oselu PDP Fesun Ipinu Lati pa Awon Olori re kan APC



Egbe oselu PDP ni o ti fesun kan egbe APC ti on se ijoba lowo pe on pinu lati pa awon kan ninu awon olori egbe re. Gege bi Daily Trust se so, esun yi ni alukoro egbe PDP, Olisa Metuh fi kan APC ni ojo ojoru, ojo kejidinlogun, oku ti a wa yii nigba ti on ba awon akoroyin soro ni Legacy House,  labuja. Gege bi iroyin ti so, egbe naa ni o daruko awon olori egbe re bii Prince Uche Secondus eni ti on se ise olori egbe naa, Ike Ekweremadu, igbákeji aare ile igbimo asofin, Godswill Akpabio, aare egbe ti o kere julo ni ile igbimo asofin ati Bello Mohammed, olori awon oko alabesekele(Board of trustees) gege bi awon ti egbe APC fe pa.
Alukoro egbe PDP ni o tesiwaju pe, bi ohunkohun ba se enikeni ninu awon olori egbe won, awon egbe oselu APC ni yio seduro fun. Okunrin naa fi kun oro re pe awon ni awon iroyin pe awon apaniyan kan ni egbe APC ti yan lati se ise naa.

16/11/2015

Aare Setan Lati Kede Awon Oluranlowo.



Aare orilèdè Naijiria ni iroyin fihan pe o ti setan lati kede awon oluranlowo pataki fun ijoba. gege bi iroyin ohun, awon ti aare fe yan sipo ni o ti ni oruko won lowo ti yio si kede oruko won laipe. Bi a ko ba gbagbe, oluranlowo pataki kan ni ijoba ti yan lati igba ti aare ti bere ise. Oruko oluranlowo pataki naa ni Femi Adesina, eni ti o je oluranlowo fun ijoba lori eto iroyin(NEWS AND PUBLICITY).

15/11/2015

AYO FAYOSE PE OMO ODUN MARUNDINLOGOTA



Gomina ipinle Ekiti ni o p omo odun marundinlogota loni ojo Aiku ojo karundinlogun, osu kokanla odun 2015. Eyi ni aworan akara oyinbo ti a won enia re se fun .

 
Akara oyinbo ojo ibi Fayose.