Egbe oselu PDP ni o ti fesun kan egbe APC ti
on se ijoba lowo pe on pinu lati pa awon kan ninu awon olori egbe re. Gege bi Daily Trust se so, esun yi
ni alukoro egbe PDP, Olisa Metuh fi kan APC ni ojo ojoru, ojo kejidinlogun, oku
ti a wa yii nigba ti on ba awon akoroyin soro ni Legacy House, labuja. Gege bi iroyin ti so, egbe naa ni o daruko awon olori egbe re
bii Prince Uche Secondus eni ti on se ise olori egbe naa, Ike Ekweremadu, igbákeji aare ile igbimo asofin, Godswill Akpabio, aare
egbe ti o kere julo ni ile igbimo asofin ati Bello Mohammed, olori awon oko
alabesekele(Board of trustees) gege bi awon ti egbe APC fe pa.
Alukoro egbe PDP ni o tesiwaju pe, bi
ohunkohun ba se enikeni ninu awon olori egbe won, awon egbe oselu APC ni yio seduro
fun. Okunrin naa fi kun oro re pe awon ni awon iroyin pe awon apaniyan kan ni
egbe APC ti yan lati se ise naa.
No comments:
Post a Comment