Okunrin afurasi ti o wa nidi ikolu ti o waye
ni Paris ni ojo eti, ojo ketala osu yii ni a gbo pe o ti dero orun. Afurasi naa,
Abdelhamid Abaaoud ti o je omo odun metadinlogbon ni iroyin fihan pe o ku ninu igbogunti
ti awon olopaa se ni apa ariwa Paris ni ojo ojoru ojo kejidinlogun, osu yii. Okunrin
ti won tii n wa tipe naa ni won damo nipa ayẹwo ara.
No comments:
Post a Comment