Ijoba orilèdè Naijiria ni o ti fesun jiji
Billionu meji dola($2bn) kan ogbeni Sambo Dasuki, okan ninu awon ajagun feyinti
ti o je oluranlowo pataki fun ijoba ana. Okunrin naa ni won so pe o ji owo naa
ninu owo ti o ye ki ijoba fi ra ohun elo ogun lati ba egbe afemisofo Boko Haramu
ja. Gege bi ohun ti ogbeni Femi Adesina ti o je oluranlowo pataki fun ijoba se
so, opolopo eniyan ti o ku ninu ikolu awon egbe afemisofo naa ni iba ma ba
isele ohun lo ti okunrin naa ba na owo naa bi o se ye.
Gege bi iroyin se so, Ogbeni Dasuki ni won
fesun kan pe o ko lati ra awon ohun ija oloro ti ijoba ana sopé ko ra lehin ti o gba owo ti o to billionu meji owo dola.
Okunrin naa ni won tun fesun kan pe o mu
ki ile-ifowo pamo ti o ga ju ni orilèdè wa, iyen central bank of Nigeria, san
owo ti o to millionu mejilelogoje($142.6 million) si apo ifowo pamo ile ise kan ti o wa ni orilèdè
United States, United Kingdom ati West Africa fun awon idi
ti ijoba ko mo.
Sa, okunrin omo ogota naa ni o ti sopé ohun
ko jebi awon esun naa.
No comments:
Post a Comment