Showing posts with label IROYIN. Show all posts
Showing posts with label IROYIN. Show all posts

02/06/2016

ONA OKO OJU IRIN ABUJA-KADUNA NI IJOBA YIO SI LAIPE.

Aare orilèdè Naijiria, Aare Muhammadu  Buhari ni yio si oju ona oko oju irin ti o to ibuso Metadinlaadowaa(187km) ni ose kini osu keje odun yii. Eyi ni minisiter fun eto irinna, Rotimi Amaechi fihan.
Nigba ti on ba awon oniroyin soro lana, ojo kini, osu kefa, lehin ti won pari idanwo akoko oju ona ohun lati idu de Kubwa, Minista naa fihan pe gbogbo nnkan lo ti to fun aare lati si oju ona ohun.
Minisiter naa ti o so pe akoko ti o daa ni oju ona ohun setan nitori o je akoko ti awon eniyan n wa ona mi n lati ma rin irin ajo ni  o salaye pe ijiroro n lo laarin ajo ti on ri si eto irinna(Ministry of transport) ati ajo Reluwe orilèdè yii (Nigerian Railway Corporation) lori iye ti awon eniyan yio ma san lati wo oko oju irin.
O tesiwaju pe, lati dabobo emi ati dukia, awon eniyan ti won ti sayewo fun pelu ami idanimo ni aye yio wa fun lati maa wo oko ni awon ibuso oko oju irin ohun. O salaye pe ise n lo lowo lati rii pe, o kere tan, awon osise eleto aabo egberun(1000) lo wa ni awon ibuso oko oju irin ohun.
Ninu oro tire, eni ti on sojuse oga ajo reluwe, Fidet Okhiria, so wipe ise n lo lowo lati ra awon oko sii.

Iroyin yii ni o jade ninu iwe iroyin TheGuardian, 02/06/2016

31/05/2016

ENIYAN MEJE KU NINU IWODE MASSOB

Eniyan meje ni iroyin fi han pe o ti ku leyin ifehonu han egbe “movement for the actualization of sovereign state of Biafra (MASSOB) ” ni Asaba, olu ilu ipinle Delta ni ojo Aje.
Gege bi eni ti on sojuse Alukoro olopaa ipinle naa, SP Charles Muka se so, olopaa meji pelu awon ti o ku nigba ti awon marun je omo egbe MASSOB. Awon olopaa meji miran tun farapa ninu isele naa. SP Muka salaye pe awon omo egbe MASSOB ni o sadede kolu awon olopaa ti ajo olopaa ipinle naa ran lati mojuto eto iwode naa eyi ti o yori si iku olopaa meji ati ìfarapa meji miran. O tesiwaju wipe awon egbe MASSOB naa lo tesiwaju lati lo kolu oko awon ologun ile wa, eyi ti o fa iku merin ninu won, ti awon mejo si dero ago olopaa.
Okunrin naa lo gba awon obi ni imọran lati kilo fun awon omo won lati topase alafia ti o bófin mu ninu ohun gbogbo ti won ba se.

Iroyin yii ni a ri ni The Guardian online 30/05/2016.

16/11/2015

OWO AWON OLOPAA TE AWON OLE TI ON FI OHUN IJA OLORO SINU BUREDI.



Awon ole kan ti won fi ohun ija oloro pamo sinu búrẹdì ja awon eniyan lole ni ajo olopaa ipinle Rivers ti fi panpe oba gbe. Oga olopaa ipinle naa, Musa Kimo fi awon aworan awon adingunjale naa han lori ero ayélujára “facebook”. O le wo awon aworan naa nisale.


Bread armed robbers1 
Bread armed robbers2
Bread armed robbers4 

15/11/2015

AYO FAYOSE PE OMO ODUN MARUNDINLOGOTA



Gomina ipinle Ekiti ni o p omo odun marundinlogota loni ojo Aiku ojo karundinlogun, osu kokanla odun 2015. Eyi ni aworan akara oyinbo ti a won enia re se fun .

 
Akara oyinbo ojo ibi Fayose.