Awon omo metadinlogbon, ni ile ìwé kan ni apa
ariwa orilèdè England ni o ti dero ile iwosan ni ojoru ojo kokanla osu
kokanla odu 2015 lehin ti awon omo naa sa dede bere aisan ti awon mi si daku.
Isele naa ni o waye ni ile ìwé Outwood Academy, ni
agbegbe oja Ripon, ariwa yorkshire. Awon omo naa ni o sa dede ṣàfihàn awon
apeere aisan ti omiran si daku. Awon
onisegun oyinbo ni a gbo pe o bojútó ninu awon omo naa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nigba ti a
gbe awon yoku lo si ile iwosan.
Awon ajo olopaa ati ajo panápaná ni o tin se iwadi
lori isele naa. Ile ìwé naa je okan ninu awon ile ìwé ti o tobi ju ni orilèdè
England, pelu Awon omo ti oto egberun meji o le igba ti ojo ori won wa laarin
odun mokanla si mejidinlogun.
No comments:
Post a Comment