12/11/2015

OKUNRIN KAN FOJU BALE EJO LORI ESUN IFIPABANILOPO



Okunrin omo odun marundinlogoji kan, Yusuf Umaru, ni o ti foju bale èjo majistreti kan ni ilu eko lojo Ojo’bo lori esun ifipabanilopo.
Okunrin afurasi naa, ni won fesun kan wipe o ba omomo iya onile re ti ko ju omo odun meedogun lo lopo nigba ti omo naa wa ki iya agba re ni akoko odun iléya ni ojo keeedogun osu kesan odun ti a wa yii. Umaru ni a gbo pe o loun ko jebi esun naa.
Agbejoro olupejo, Iyabode Johnson, ni o ni esun naa lodi si Abala 137, ofin iwa odaran ilu Eko ti odun 2011 ti o si ni ijiya nla ninu.
Abala 137 ni o so wipe enikeni ti o ba ba omode sun jebi esun “FELONY” ti o si ye lati lo gbogbo ìyókù ojo aye re lewon (life imprisonment).
Adajo A.A Oshiniyi faaye beeli sile fun olujejo Ni iye owo ti o to egberun lona igba naira (200,000) pelu oni duro meji ti o Ni ile si Agbegbe Ikorodu magisterial district. Awon oni dúró naa si gbodo ni ise gidi lowo.

No comments:

Post a Comment