11/11/2015

DSS GBE AFURASI ODARAN MEJI MIN LO SILE EJO LORI IJINIGBE OGBENI OLU FALAE



Ni ojo isegun, eka to n mojuto abo ilu, iyen Department of state security services (DSS) ni o gbe afurasi odaran meji miran lo si iwaju ile ejo giga ti ilu Akure lori esun ijinigbe akowe ijoba Ana, Chief Olu Fálaè̀. Awon afurasi naa ti oruko won je Babawaro Kato ati Abdulkadir Umar ni won mu ni Àbùjá lehin itanilolobo. Awon afurasi odaran naa ni pelu awon marun min ti won ti mu tele lori esun naa ni won gbe lo siwaju ile ejo giga ipinle Ondó ti o fi ilu Akure se Ibu joko.
Awon esun ti won fi kan awon odaran naa ni wipe won ji Chief Olu Fálaè gbe ni ojo Aje, ojo kokanlelogun, osu kesan odun 2015 ti won ko si fi okunrin naa sile titi won fi ri pe awon gba millionu marun naira ati wipe won ja okunrin naa lolè egberun lona marundilogun naira(#15,000) ati ero alagbeeka re nigba ti won kaa mo pelu ìbon, ada ati awon ohun ija oloro min. Awon agbejoro olupejo so wipe awon iwa naa tako Abala keji ofin ti o tako ijinigbe ni orilèdè wa.
Awon odaran mejeeji ni o so wipe awon ko jebi esun naa.
Olori agbejoro olupejo, Akinladapo Ogunleye, ni o toro aye die lowo ile ejo lati fi aye sile fun won lati ko eleri jo lori esun naa. Adajo William Polymide, ti on gbo ejo naa ni o tewo gba aba naa ti o si sun igbejo miran si ojo keji, osu kejila odun ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment