ORILEDE
ALAWO DUDU MEJI NI YIO PADE NI IDIJE ASEKAGBA AWON ODO TI OJO ORI WON KO JU
METADINLOGUN (U17)
Orilèdè naijiria
ni yio koju orilèdè mali ni asekagba boolu alafesegba awon oje wewe ti ojo
ori won ko ju odun metadinlogun lo, iyen, FIFA U-17 world cup Chile 2015.
Awon odo orilèdè mali ni o na akegbé won lati orilèdè Belgium ni
ami ayo meta si okan ni ipele to kangun si asekagba nigba ti orilèdè naijiria
na orilèdè mesiko ni ami ayo merin si meji.
Awon
orilèdè mejeeji ti o wa lati ile alawo dudu ni yio pade ni ipele asekagba ìdíje
naa ni ojo Aiku ojo kejo osu belu odun 2015 ni ago meje ale.
NJE
OMO? Wipe odun mejilelogun sehin ni orilèdè meji lati kontineeti kanna ti
pade gbeyin ni ipele asekagba ìdíje yii? Orilèdè naijiria ati orilèdè
Ghana ni o pade ninu eyi ti orilèdè naijiria ti jawe olúborí lati gba ife
eye naa fun igba akoko.
No comments:
Post a Comment