AJO OLOOPA IPINLE DELTA FO ILEISE TI WON TIN
LO OMODE NILOKULO (human trafficking).
Iroyin fidi
e mule pe Alkali Baba Usman, ti o je oga ilé-iṣé olopaa ipinle delta fidi isele
na mule nigbati on ba awon ako royin soro ni ojo aje, ojo kokandinlogun, osu
owara odun 2015. Gege bo se so, awon olopaa eka ti on moju to iwa odaran, iyen eka
awon Special Anti-Robbery Squad (SARS), ti ipinle na ni o gbe igbese leyin itanilolobo nipa ile ise ti won tin
lo omo ni ilokulo lodi si ofin, ti won si mu obirin kan ti oruko re je Nkiru
Asouza ati oko re, Chidiebele Udeagbala.
Okunrin na fihan ninu ìtàkurọ̀sọ re pelu awon oniroyin
pe awon afurasi odaran na jewo pe looto làwon hu awon iwa ti o bófin mu ohun,
ti won si ran awon olopaa SARS lowo lo si ipinle Anambra nibi ti won ti mu
obirin kan, Mary Bassey Okon ti won si gba awon omo merin ti ojo ori won ko ti
ju marun lo sile lowo re.
Oga olopaa
na tesiwaju pe nipa ìtàkurọ̀sọ sii pelu awon afurasi odaran na, awon olopaa de
ipinle Akwa-ibom nibi ti won ti mu Ekaete Sunday, Etieno Mary Bassey, Stella
John ti won si gba awon omo meji sile lowo won.
Usman so wipe Chidima Johnson ati omo mefa ni
won fa le ajo ton mojuto eto obinrin lowo, iyen, ministry
for wonen affairs. Nigba ti won fa Nancy Atume le awon obi
re lowo.
No comments:
Post a Comment