31/05/2016

ENIYAN MEJE KU NINU IWODE MASSOB

Eniyan meje ni iroyin fi han pe o ti ku leyin ifehonu han egbe “movement for the actualization of sovereign state of Biafra (MASSOB) ” ni Asaba, olu ilu ipinle Delta ni ojo Aje.
Gege bi eni ti on sojuse Alukoro olopaa ipinle naa, SP Charles Muka se so, olopaa meji pelu awon ti o ku nigba ti awon marun je omo egbe MASSOB. Awon olopaa meji miran tun farapa ninu isele naa. SP Muka salaye pe awon omo egbe MASSOB ni o sadede kolu awon olopaa ti ajo olopaa ipinle naa ran lati mojuto eto iwode naa eyi ti o yori si iku olopaa meji ati ìfarapa meji miran. O tesiwaju wipe awon egbe MASSOB naa lo tesiwaju lati lo kolu oko awon ologun ile wa, eyi ti o fa iku merin ninu won, ti awon mejo si dero ago olopaa.
Okunrin naa lo gba awon obi ni imọran lati kilo fun awon omo won lati topase alafia ti o bófin mu ninu ohun gbogbo ti won ba se.

Iroyin yii ni a ri ni The Guardian online 30/05/2016.

No comments:

Post a Comment