Aare orilèdè Naijiria, Aare Muhammadu Buhari ni yio si oju ona oko oju irin ti o to
ibuso Metadinlaadowaa(187km) ni ose kini osu keje odun yii. Eyi ni minisiter
fun eto irinna, Rotimi Amaechi
fihan.
Nigba ti on ba awon oniroyin soro lana, ojo
kini, osu kefa, lehin ti won pari idanwo akoko oju ona ohun lati idu de Kubwa,
Minista naa fihan pe gbogbo nnkan lo ti to fun aare lati si oju ona ohun.
Minisiter naa ti o so pe akoko ti o daa ni oju
ona ohun setan nitori o je akoko ti awon eniyan n wa ona mi n lati ma rin irin
ajo ni o salaye pe ijiroro n lo laarin
ajo ti on ri si eto irinna(Ministry of transport) ati ajo Reluwe orilèdè
yii (Nigerian Railway
Corporation) lori iye ti awon eniyan yio ma san lati wo
oko oju irin.
O tesiwaju pe, lati dabobo emi ati dukia, awon
eniyan ti won ti sayewo fun pelu ami idanimo ni aye yio wa fun lati maa wo oko ni
awon ibuso oko oju irin ohun. O salaye pe ise n lo lowo lati rii pe, o kere
tan, awon osise eleto aabo egberun(1000) lo wa ni awon ibuso oko oju irin ohun.
Ninu oro tire, eni ti on sojuse oga ajo
reluwe, Fidet Okhiria, so wipe ise n lo lowo lati ra awon oko sii.
Iroyin yii ni o jade ninu iwe iroyin
TheGuardian, 02/06/2016
No comments:
Post a Comment