31/05/2016

AWON AGBEBON PA ENIYAN MEFA NI RIVERS

Eniyan mefa lo ti doloogbe ni Awujo ibaa, ni agbegbe ijoba ibile Emohua ni ipinle Rivers nigba ti awon afurasi elégbe okunkun kan ti won pe ni “Greenlanders” kolu ilu naa lale ojo Aiku, ojo kokandinlogun osu yii.
Gege bi iroyin se so, Ikolu naa lo waye latari ifagagbaga egbe okunkun naa ati egbe okunkun “icelanders” awon eniyan to ku naa si je omo egbe okunkun Icelanders.
Alukoro olopaa ipinle rivers, Ogbeni Ahmad Muhammed nio fidi isele naa mule ti o si fihan pe egbe okunkun meji lo n ja.
Gege bo se so, Alafia ni o tii n pada si Agbegbe naa latari bi awon olopaa se tete de ilu naa.
Olutoju ipo Alaga ijoba ibile Emohua, Ogbeni John Wokoma ni o ti ro awon eniyan lati pada sile won, ati pe ijoba ibile naa yio ri si abo lori Emi ati dukia ni agbegbe naa.

Iroyin yii la ri ni punchng, 30/05/2016

No comments:

Post a Comment