07/12/2015

Egbe APC Kaduna pin si meji.


Egbe All Progressive government(APC) ipinle Kaduna ni o ti pin si meji lehin nnkan bi osu mefa ti egba naa gbajoba ipinle ohun. Gege bi iroyin se so, egbe titun naa ni o ni awon eniyan jànkan bii akowe ijoba tele, Dr Hakeem Baba-Ahmed, Alaga ANPP tele, Alhaji Kabir Umar, koomisoanna tele eto eko,  ogbeni Tom mataimaki Maiyashi, Alhaji Lawal     Maiturare, Nasiru Ahmed ati Murtala Abubakar.
Egbe titun naa ni na ni won pe oruko re ni ‘True APC’ ti awon omo egbe naa si fesun kan ijoba Gomina Nasir El-Rufai, pe ijoba okunrin naa ni on se ohun ti o yato si ohun ti egbe awon duro fun. Gege bi egbe titun naa ti so, iyato(Change) ni egbe naa duro fun, ti awon ara ilu si ye ko ri iyato naa ninu ijoba egbe awon, sugbon ti ijoba Nasir El-Rufai  ko tele ilana egbe naa.
Sa, awon olori egbe APC ni o ti fowosi awon ilana  ti Gomina Nasir El-Rufai n tele pe o ba ilana egbe awon mu.

1 comment: