05/12/2015

EFCC bere iwadi $200m owo ohun ija ogun.

Eka ti on gbogun ti iwa jegudujera lorilede wa, iyen Economic and financial crimes commission(EFCC) ni o ti bere iwadii lori rira ohun elo ogun ti o to millionu meji dola($200m) laarin okunrin kan ati ijoba orilèdè ukraine, eyi ni o waye latari iwadi ti ajo naa n se lori ohun ija ogun ti ijoba ana ra.
Gege bi iroyin se so, iwadi fi han pe okunrin onisowo naa ni o soju ijoba ninu rira awon ohun elo ogun ti o to igba millionu naira, sugbon ti awon ohun elo ogun naa ko ti de orilèdè wa. Gege bi iroyin ohun, okunrin naa ni o ti san owo rira awon ohun ija ogun naa fun orilèdè Ukraine sugbon ti ko je ki awon tohun kowa nitori o  ni ijoba je ohun ni awon owo kan.
Sa, ajo EFCC ti bere iforowanilenuwo pelu okunrin naa ni ana, ojo eti, bee si ni iwadi n tesiwaju lori esun naa.

No comments:

Post a Comment