04/12/2015

Arun Ebola -- Liberia bere kika ojo mejilelogun



Kika ojo mejilelogoji lati kede orilèdè Liberia gege bi okan ninu awon orilèdè ti o ti bo lowo arun Ebola ni igba keta ni o ti bere ni ojo ojobo, ojo keta osu yii. Gege bi iroyin se so, kika naa ni o bere lehin ti ile iwosan kan ti won tin toju arun naa tu awon meji ti o se ku sibe sile lehin itoju.
Bi a ko ba gbagbe, orilèdè naa ni ajo WHO ti kede pe o bo lowo arun Ebola nigba meji ki o to di akoko yii, ti o si je pe ni igba mejeeji ni arun naa pada jeyo.
Arun Ebola ni o ti pa egberun Mokanla o le odunrun(11,300) eniyan lati  igba ti arun naa ti bere ni osu kejila odun 2013, eyi ti o mu akoko naa je igba ti arun naa pa eniyan julo lati odun 1976 ti  o ti di mimo.

1 comment: