03/12/2015

Ijoba ge owo itanran MTN



Eka ti on mojuto eto ibaraenisoro lorilede wa, iyen Nigerian Communications Commission(NCC) ni o ti ge owo itanran ti ajo naa ni ki ile ise ibaraenisoro MTN san. Eleyi ni o waye leyin ti ile ise MTN ge awon ila ero ibaraenisoro ti ko lakosile lodo ile ise ohun (unregistered SIM). Bi a ko ba gbagbe, ile ise MTN ni ajo NCC ni ko san owo itanran billionu marun o le meji dola ($5.2 billion) ni osu kewa odun yii lehin ti ile ise naa ko lati ja awon ila ibaraenisoro ti ko lasosile nigba ti gbèdéke ojo ti NCC fun won lati fi ja awon ila naa pe.
Gege bi iroyin lati odo ile ise MTN, ajo NCC ni o ti ge owo itanran naa si billionu meta o le merin dola ($3.4billion) lati billionu marun ti won fun won tele ti ajo naa si gbodo wa owo naa san ki ojo kokanlelogbon, osu yii to koja.
Sa, ile ise naa ti fihan pe awon yio pe ipade laarin gbogbo awon ti oro naa kan lati le jiroro lori owo itanran ohun.

No comments:

Post a Comment