03/12/2015

Awon oko oju omi pelu oku Eniyan farahan ni Japan.



Awon oko oju omi bii metala pelu awon oku ti o to mokanlelogun  ni o ti n farahan ni orilèdè Japan lati nnkan bi osu kewa odun yii.
Gege bi iroyin se so, alukoro awon eso oju omi fi oro yii han nigba ti o so pe oko oju omi bii metala ni o ti farahan ni orilèdè naa lati osu kewa  odun pelu awon oku ti iye won to mokanlelogun lapapo. Gege bi iroyin se so, awon oko naa ni o see se ko je lati orilèdè north korea ni won ti wa, ti o si see se ki won je ara awon jagunjagun ti ijoba orilèdè naa ran nise lati lo peja, eyi ti ijoba orilèdè naa se lati mu adínkù ba ebi ati lati mu ki ounje po sii laarin ilu. Ohun ti o  pa awon eniyan naa ni enikeni ko tii mo, sugbon awon kan gbagbo pe o see se ko je ebi tabi otutu ni o pa awon eniyan naa.
Gbogbo awon oko naa ni iroyin fi han pe ori omi “sea of Japan” ni won ti ri won.

No comments:

Post a Comment