04/12/2015

Amuneke yio maa ran Garuba lowo – NFF



Akonimoogba egbe agbaboolu U-17 ti o gba ife eye idije agbaye ni orilèdè Chile, iyen Emmanuel Amuneke, ni ajo ti on ri si oro ere boolu lorilede wa, iyen Nigeria football federation (NFF), ti fun ni ipo akonimoogba egbe agbaboolu U-20.
Gege bi iroyin ti o ti odo ajo NFF jade, Manu Garuba ni yio si duro ni ipo re gege  bi akonimoogba U-20 nigba ti Amuneke yio duro ni ipo re gege bi akonimoogba U-17, ti yio si je igbákeji fun Manu Garuba ni ipele U-20.
Gege bi ohun ti Amaju Pinnick ti o je Aare NFF so, Manu Garuba ati Amuneke ni o ni ibasepo ti o dara laarin ara won eyi ti yio ran ere boolu lowo lorilede yii.
Bi a ko ba gbagbe, ogbeni Amuneke ni igbákeji Manu Garuba nigba ti egbe agbaboolu U-17 gba ife eye agbaye ni orilèdè United Arab Emirates(UAE) ni odun 2013.

No comments:

Post a Comment