24/11/2015

Won ri ado oloro ninu apoti idalenu(Dustbin) ni France.



Awon olopaa Paris ni on se ayewo ohun kan ti o jo ado oloro(Bomb) ti awon ti on tu ilu se ri ninu apoti ti won ko idoti si(Dustbin) ni agbegbe Montrouge district, ni ana. Gege bi iroyin se so, ado oloro naa ni o jo eyi ti awon ti o se akolu Paris lo ni ojo eti, ojo ketala osu yii. Iroyin ti o te wa lowo fihan pe Salah Abdeslam, okan ninu awon ti won sakolu si Paris, ti awon agbófinró orilèdè naa sii wa ni o se see ki o gba ibe koja ni ojo naa. Gege bi iwadi awon olopaa, ado oloro naa ni ko ni “detonator”, ohun ti enikeni ti o ba gbee dani gbodo ni ki o to le yin bombu ohun, eyi lo mu ki awon kan ro pe o se see ki okunrin naa ni awon ipenija kan pelu ado oloro na,eyi ti ko je ko le yin ni ojo naa.
Sa, iwadii si n te siwaju lori oro naa, bee na ni won si n wa Salah Abdeslam ni orilede France ati Belgium.

No comments:

Post a Comment