26/11/2015

Owo te odaran nibi ti o tin dárayá ninu ile onile.



Omo odun mejidinlogbon kan, Olamilekan Olaoluwa,  ni owo awon agbófinró te ni ojo Aiku, ojo kejilelogun osu yii nigba ti on dárayá ninu ile ti o ti lo jale. Gege bi iwe iroyin Punch se so, omokùnrin naa ni o ja wonu ile kan oni yara meji, ti o wa ni agbegbe oju ona Brickfield, ni nnkan bi aago meji osan ojo Aiku. Gege bi iroyin se so, nigba ti omokùnrin ti a bi ni Kwara naa wonu ile naa, ko ba awon onile eyi ti o fun laye lati se ohun ti o wu. Omokùnrin naa ni a gbo pe o yo ero amohun-maworan ti egbe ogiri(Plasma Television) ti iye re to Aadojo lona egberun naira(N150,000), aago ilewo meji ti iye re to aadota lona egberun naira(N50,000), awon aso awotele ti iye re to egberun mewa naira(N10,000) ati fóònù alágbèéká ti iye re to egberun marun naira (N5,000). Gege bi iroyin se so, nigba ti omokùnrin naa ji gbogbo nnkan wonyi tan, o bere si dárayá pelu bi o se mu igó Malt kan ninu ero tin mu nnkan tutu ti o si bere si ni mu, ibe si ni okan ninu awon ti on gbe ile naa ti de baa ti o si fariwo ta, eyi ti o mu kawon eniyan ro wa sibe. Omokùnrin naa ni o ti wa nii odo  awon olopaa, ti o si ti foju bale ejo ni ojo isegun pelu esun merin bii fifo ile onile, biba nnkan je, dida alafia ilu ru, ati ole jija.
                                                                            

No comments:

Post a Comment