22/11/2015

AWON OLOPAA MU AWON OKUNRIN TI ON BA ARA WON LAJOSEPO (GAY).



Awon olopaa ni Asaba, olu ilu ipinle Delta, ni o ti mu awon omo ile iwe okunrin mokanlelogun ti won fura si pe won ba okunrin egbe won lajosepo (Homosexual). Alukoro Ile ise olopaa ipinle naa, Arabirin Celestina Kalu, ni o fidi oro naa mule.
Bi a ko ba gbagbe, ofin orilèdè Naijiria ni o tako ki okunrin maa ba okunrin se tabi ki obirin maa ba obirin se, ti iru iwa bee si ni ijiya ninu gege bi ofin.

No comments:

Post a Comment