23/11/2015

OWO OLOPAA TE AFURASI MEJO LORI ESUN IPANYAN



Eka ajo olopaa ti ipinle Eko ni o ti ko afurasi odaran Mejo lori esun ipaniyan. Gege bi iroyin se so, awon afurasi naa, Animashaun Akeem, Qudus Atakoro, Muritala Oyejobi, Abduranon Onisemo,Tabiu Mujib, Iyaniwura Idris, Tayo Oladimeji, ati Segun Adeyemi ni owo awon olopaa te lori esun pipa Akeem Ajanaku ni Enu – Owa/Ido Oluwo ni agbegbe ori omi ipinle Eko.
Awon afurasi odaran naa ni awon Olopaa mu nibi isele naa.
Gege bi iroyin se so, ni ojo keeedogun osu yii, ni nnkan bi aago kan osan ni awon omota kan pelu orisirisi ohun ija oloro kolu ogbeni Akeem Ajanaku, eyi ti o mu ki o dero ile iwosan  Lagos Island General Hospital, nibi ti o ti pada ku.
Tayo Oladimeji, okan ninu awon afurasi ti owo olopaa te ni o so pe ohun ko mo nnkan kan nipa esun naa.
Sa, ajo olopaa ti tari ejo naa si eka ti on gbogun ti iwa odaran laarin ilu, iye special Anti – robbery Squad, eka ti ipinle Eko, nibi ti iwadi yio ti ma te siwaju.


No comments:

Post a Comment